8. Nigbati nwọn si gbé oju wọn soke, nwọn kò ri ẹnikan, bikoṣe Jesu nikan.
9. Bi nwọn si ti nti ori òke sọkalẹ, Jesu kìlọ fun wọn pe, Ẹ máṣe sọ̀rọ iran na fun ẹnikan, titi Ọmọ-enia yio fi tun jinde kuro ninu okú.
10. Awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si bi i lẽre, wipe, Ẽṣe ti awọn akọwe ha fi wipe, Elijah ni yio tètekọ de?