13. Nigbana li o yé awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Johanu Baptisti li ẹniti o nsọ̀rọ rẹ̀ fun wọn.
14. Nigbati nwọn si de ọdọ ijọ enia, ọkunrin kan si tọ ọ wá, o kunlẹ fun u, o si wipe,
15. Oluwa, ṣãnu ọmọ mi, nitori o ni warapa, o si njoro gidigidi: nigba pupọ ni ima ṣubu sinu iná, ati nigba pupọ sinu omi.
16. Mo si mu u tọ̀ awọn ọmọ-ẹhin rẹ wá, nwọn kò si le mu u larada.