77. Lati fi ìmọ igbala fun awọn enia rẹ̀ fun imukuro ẹ̀ṣẹ wọn,
78. Nitori iyọ́nu Ọlọrun wa; nipa eyiti ìla-õrùn lati oke wá bojuwò wa,
79. Lati fi imọlẹ fun awọn ti o joko li òkunkun ati li ojiji ikú, ati lati fi ẹsẹ wa le ọ̀na alafia.
80. Ọmọ na si dàgba, o si le li ọkàn, o si wà ni ijù titi o fi di ọjọ ifihàn rẹ̀ fun Israeli.