Nigbana li obinrin ara Samaria na wi fun u pe, Ẽti ri ti iwọ ti iṣe Ju, fi mbère ohun mimu lọwọ mi, emi ẹniti iṣe obinrin ara Samaria? nitoriti awọn Ju ki iba awọn ara Samaria da nkan pọ̀.