Lori eyi li awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ de, ẹnu si yà wọn, pe o mba obinrin sọ̀rọ: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o wipe, Kini iwọ nwá? tabi, Ẽṣe ti iwọ fi mba a sọ̀rọ?