1. NI ijọ kẹta a si nṣe igbeyawo kan ni Kana ti Galili; iya Jesu si mbẹ nibẹ̀:
2. A si pè Jesu ati awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pẹlu, si ibi igbeyawo.
3. Nigbati waini si tan, iya Jesu wi fun u pe, Nwọn kò ni waini.
4. Jesu wi fun u pe, Kini ṣe temi tirẹ, obinrin yi? wakati mi kò iti de.
5. Iya rẹ̀ wi fun awọn iranṣẹ pe, Ohunkohun ti o ba wi fun nyin, ẹ ṣe e.
6. Ikoko okuta omi mẹfa li a si gbé kalẹ nibẹ̀, gẹgẹ bi iṣe ìwẹnu awọn Ju, ọkọkan nwọn gbà to ìwọn ládugbó meji tabi mẹta.
7. Jesu wi fun wọn pe, Ẹ pọn omi kun ikoko wọnni. Nwọn si kún wọn titi de eti.
8. O si wi fun wọn pe, Ẹ bù u jade nisisiyi, ki ẹ si gbé e tọ̀ olori àse lọ. Nwọn si gbé e lọ.