Ati gbogbo ilu pẹtẹlẹ̀ na, ati gbogbo ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, ti Mose kọlù pẹlu awọn ọmọ alade Midiani, Efi, ati Rekemu, ati Suri, ati Huri, ati Reba, awọn ọmọ alade Sihoni, ti ngbé ilẹ na.