Nitorina li o sọ fun awọn onṣẹ Benhadadi pe, Wi fun oluwa mi ọba pe, ohun gbogbo ti iwọ ranṣẹ fun, sọdọ iranṣẹ rẹ latetekọṣe li emi o ṣe: ṣugbọn nkan yi li emi kò le ṣe. Awọn onṣẹ na pada lọ, nwọn si tun mu èsi fun u wá.