Ṣugbọn pupọ ninu awọn alufa ati awọn ọmọ Lefi, pẹlu awọn olori awọn baba ti iṣe alàgba, ti nwọn ti ri ile atetekọṣe, nwọn fi ohùn rara sọkun, nigbati a fi ipilẹ ile yi lelẹ li oju wọn, ṣugbọn awọn pupọ si ho iho nla fun ayọ̀: