17. Ni ìgba mẹta li ọdún ni gbogbo awọn ọkunrin rẹ yio farahàn niwaju Oluwa JEHOFA.
18. Iwọ kò gbọdọ ta ọrẹ ẹ̀jẹ ẹbọ mi ti on ti àkara wiwu; bẹ̃li ọrá ẹbọ ajọ mi kò gbọdọ kù titi di ojumọ́.
19. Akọ́ka eso ilẹ rẹ ni ki iwọ ki o múwa si ile OLUWA Ọlọrun rẹ. Iwọ kò gbọdọ bọ̀ ọmọ ewurẹ ninu warà iya rẹ̀.
20. Kiyesi i, emi rán angeli kan siwaju rẹ lati pa ọ mọ́ li ọ̀na, ati lati mú ọ dé ibi ti mo ti pèse silẹ.
21. Kiyesi ara lọdọ rẹ̀, ki o si gbà ohùn rẹ̀ gbọ́, máṣe bi i ninu; nitoriti ki yio dari irekọja nyin jì nyin, nitoriti orukọ mi mbẹ lara rẹ̀.
22. Ṣugbọn bi iwọ o ba gbà ohùn rẹ̀ gbọ́ nitõtọ, ti iwọ si ṣe gbogbo eyiti mo wi; njẹ emi o jasi ọtá awọn ẹniti nṣe ọtá nyin, emi o si foró awọn ti nforó nyin.
23. Nitoriti angeli mi yio ṣaju rẹ, yio si mú ọ dé ọdọ awọn enia Amori, ati awọn Hitti, ati awọn Perissi, ati awọn ara Kenaani, awọn Hifi, ati awọn Jebusi: emi a si ke wọn kuro.
24. Iwọ kò gbọdọ tẹriba fun oriṣa wọn, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ sìn wọn, ki o má si ṣe gẹgẹ bi iṣe wọn: bikoṣepe ki iwọ ki o fọ́ wọn tútu, ki iwọ ki o si wó ere wọn palẹ.