GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si rìn lati ijù Sini lọ, ni ìrin wọn, gẹgẹ bi ofin OLUWA, nwọn si dó ni Refidimu: omi kò si si fun awọn enia na lati mu.